Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 12:18-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí èyí ni ìjọ ènìyàn sì ṣe lọ pàdé rẹ̀, nítorí tí wọ́n gbọ́ pé ó ti ṣe iṣẹ́ àmì yìí.

19. Nítorí náà àwọn Farisí wí fún ara wọn pé, “Ẹ kíyèsi bí ẹ kò ti lè borí ní ohunkóhun? Ẹ wo bí gbogbo ayé ti ń wọ́ tọ̀ ọ́!”

20. Àwọn Gíríkì kan sì wà nínú àwọn tí ó gòkè wá láti sìn nígbà àjọ:

21. Àwọn wọ̀nyí ni ó tọ Fílípì wá, ẹni tí í ṣe ará Bẹtisáídà tí Gálílì, wọ́n sì ń bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Alàgbà, àwa ń fẹ́ rí Jésù!”

22. Fílípì wá, ó sì sọ fún Ańdérù; Ańdérù àti Fílípì wá, wọ́n sì sọ fún Jésù.

23. Jésù sì dá wọn lóhùn pé, “Wákàtí náà dé, tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.

24. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí kò ṣe pé àlìkámà bá bọ́ sí ilẹ̀, tí ó bá sì kú, ó wà ní òun nìkan; ṣùgbọ́n bí ó bá kú, a sì so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso.

25. Ẹni tí ó bá fẹ́ ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù; ẹni tí ó bá sì kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ láyé yìí ni yóò sì pa á mọ́ títí ó fi di ìyè àìnípẹ̀kun.

26. Bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, kí ó máa tọ̀ mí lẹ́yìn: àti níbi tí èmi bá wà, níbẹ̀ ni ìránṣẹ́ mi yóò wà pẹ̀lú: bí ẹnikẹ́ni bá ń sìn mí, òun ni Baba yóò bu ọlá fún.

27. “Ní ìsinsin yìí ni a ń pọ́n ọkàn mi lójú; kínni èmi ó sì wí? ‘Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí’? Rárá, ṣùgbọ́n nítorí èyì ni mo ṣe wá sí wákàtí yìí.

28. Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo!”Nígbà náà ni ohùn kan ti ọ̀run wá, wí pé, “Èmi ti ṣe é lógo!”

29. Nítorí náà ìjọ ènìyàn tí ó dúró níbẹ̀, tí wọ́n sì gbọ́ ọ, wí pé, àrá ń sán: àwọn ẹlòmíràn wí pé, “Ańgẹ́lì kan ni ó ń bá a sọ̀rọ̀.”

30. Jésù sì dáhùn wí pé, “Kì í ṣe nítorí mi ni ohùn yìí ṣe wá, bí kò ṣe nítorí yín.

31. Ní ìsinsin yìí ni ìdájọ́ ayé yìí dé: nísinsin yìí ni a ó lé aládé ayé yìí jáde.

32. Àti èmi, bí a bá gbé mi sókè èmi ó fa gbogbo ènìyàn sọ́dọ̀ ara mi!”

Ka pipe ipin Jòhánù 12