Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 12:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà, nígbà tí àjọ ìrékọjá ku ìjọ́ mẹ́fà, Jésù wá sí Bẹ́tanì, níbi tí Lásárù wà, ẹni tí ó ti kú, tí Jésù jí dìde kúrò nínú òkú.

2. Wọ́n sì se àṣè alẹ́ fún un níbẹ̀: Màtá sì ń ṣe ìránṣẹ́: ṣùgbọ́n Lásárù Jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó jókòó níbi tábìlì rẹ̀.

3. Nígbà náà, Màtá mú òróró ìkunra nádì, òṣùwọ̀n lítà kan, àìlábùlà, olówó iyebíye, ó sì ń fi kun Jésù ní ẹṣẹ̀, ó sì ń fi irun orí rẹ̀ nu ẹṣẹ̀ rẹ̀ nù: ilẹ̀ sì kún fún òórùn ìkunra náà.

4. Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Júdásì Isíkáríótù, ọmọ Símónì ẹni tí yóò fi í hàn, wí pé,

5. “Èé ṣe tí a kò ta òróró ìkunra yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó idẹ kí a sì fi fún àwọn talákà?”

6. Ṣùgbọ́n ó wí èyí, kì í ṣe nítorí tí ó náání àwọn talákà; ṣùgbọ́n nítorí tí ó jẹ́ olè, òun ni ó sì ní àpò, a sì máa gbé ohun tí a fi sínú rẹ̀.

7. Nígbà náà ni Jésù wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, ó ṣe é sílẹ̀ de ọjọ́ ìsìnkú mi.

8. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin sáà ní talákà pẹ̀lú yín; ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.”

9. Nítorí náà, ìjọ ènìyàn nínú àwọn Júù ni ó mọ̀ pé ó wà níbẹ̀; wọ́n sì wá, kì í ṣe nítorí Jésù nìkan, ṣùgbọ́n kí wọn lè rí Lásárù pẹ̀lú, ẹni tí ó ti jí dìde kúrò nínú òkú.

10. Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lásárù pẹ̀lú;

11. Nítòrí pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù jáde lọ, wọ́n sì gbà Jésù gbọ́.

12. Ní ijọ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jésù ń bọ̀ wá sí Jérúsálẹ́mù.

13. Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé,“Hòsánnà!”“Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀wá ní orúkọ Olúwa, ọba Ísríẹ́lì!”

14. Nígbà tí Jésù sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ógùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

15. “Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Síónì;Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá,Ó jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́ktẹ́.”

Ka pipe ipin Jòhánù 12