Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì ni Ọ̀rọ̀ náà.

2. Òun ni ó sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní àtètèkọ́ṣe.

3. Nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo; lẹ́yìn rẹ̀ a kò sì dá ohun kan nínú ohun tí a ti dá.

4. Nínú rẹ̀ ni ìyè wà, ìyè yìí náà sì ni ìmọ́lẹ̀ aráyé,

5. Ìmọ́lẹ̀ náà sì ń mọ́lẹ̀ nínú òkùnkùn, òkùnkùn kò sì borí rẹ̀.

6. Ọkùnrin kan wà tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; orúkọ ẹni tí ń jẹ́ Jòhánù.

7. Òun ni a sì rán fún ẹ̀rí, kí ó lè ṣe ẹlẹ́rìí fún ìmọ́lẹ̀ náà, kí gbogbo ènìyàn kí ó lè gbàgbọ́ nípaṣẹ̀ rẹ̀.

8. Òun fúnrarẹ̀ kì í ṣe Ìmọ́lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n a rán an wá láti ṣe ẹlẹ́rìí fún Ìmọlẹ̀ náà.

9. Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ ń bẹ tí ń tan ìmọ́lẹ̀ fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wá sí ayé.

10. Òun sì wà ní ayé, àti pé, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a sì ti dá ayé, ṣùgbọ́n ayé kò sì mọ̀ ọ́n.

Ka pipe ipin Jòhánù 1