Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jákọ́bù 3:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nítorí níbi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.

17. Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsáájú, a sì máa sọ òtítọ́.

18. Àwọn tí ó ń ṣíṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.

Ka pipe ipin Jákọ́bù 3