5. Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn talákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ?
6. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu talákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n ẹ̀yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́?
7. Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?
8. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára.
9. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsáájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin.
10. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀.
11. Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Má ṣe ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Má ṣe pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.
12. Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́.