Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 8:5-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ańgẹ́lì náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.

6. Àwọn ańgẹ́lì méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.

7. Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀: Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ̀ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ̀ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jónà.

8. Ańgẹ́lì kéjì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òké-ńlá tí ń jóná, sínú òkun: ìdámẹ̀ta òkun si di ẹ̀jẹ̀;

9. Àti ìdámẹ̀ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ̀ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.

10. Ańgẹ́lì kẹ́ta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ̀ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi;

11. A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ni ìwọ̀, ìdámẹ̀ta àwọn omi sì di ìwọ̀, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.

12. Ańgẹ́lì kẹ́rin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ̀ta òòrùn, àti ìdámẹ̀ta òṣùpá, àti ìdámẹ̀ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ̀ta wọn lè ṣóòkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ̀ta rẹ̀, àti òru báka náà.

13. Mo sì wò, mo sì gbọ́ idí kan tí ń fò ni àárin ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn ańgẹ́lì mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”

Ka pipe ipin Ìfihàn 8