Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 8:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kéje, ìdákẹ́ rọ́rọ́ sì wà ní ọ̀run níwọ́n ààbọ̀ wákàtí kan.

2. Mo sì rí àwọn ańgẹ́lì méje tí wọn dúró níwájú Ọlọ́run; a sì fi ìpè méje fún wọn.

3. Ańgẹ́lì mìíràn sì wá, ó sì dúró ti pẹpẹ, ó ní àwo tùràrí wúrà kan a sì fi tùràrí púpọ̀ fún un, láti máa fí kún àdúrà gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ lórí pẹpẹ, pẹpẹ wúrà tí ń bẹ níwájú ìtẹ́.

4. Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn-mímọ́ sì gòkè lọ ṣíwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ ańgẹ́lì náà wá.

5. Ańgẹ́lì náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé: A sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì.

6. Àwọn ańgẹ́lì méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.

7. Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀: Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ̀ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ̀ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jónà.

8. Ańgẹ́lì kéjì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òké-ńlá tí ń jóná, sínú òkun: ìdámẹ̀ta òkun si di ẹ̀jẹ̀;

Ka pipe ipin Ìfihàn 8