Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 2:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di i mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.

26. Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí o sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi o fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè:

27. ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn;gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun-èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi.

28. Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un.

29. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Ka pipe ipin Ìfihàn 2