Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 2:18-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. “Àti sí Ańgẹ́lì ìjọ ní Tíátírà kọ̀wé:Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́ iná, tí ẹṣẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:

19. Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí iṣàájú lọ.

20. Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sì ọ: Nítorí tí ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún obìnrin Jésébẹ́lì tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípaṣ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rúbọ sì òrìṣà.

21. Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.

22. Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn.

23. Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn: èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

24. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tíátírà, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pe ni ohun ìjìnlẹ̀ Sàtánì, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín:

25. Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di i mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.

26. Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí o sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi o fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè:

27. ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn;gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun-èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi.

28. Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un.

29. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Ka pipe ipin Ìfihàn 2