Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 17:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti Ọba àwọn ọba: Àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtọ́ yóò sì sẹ́gun pẹ̀lú.”

15. Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti oníruru èdè ni wọ́n.

16. Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò koríra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòòhò, wọn ó sì jẹ ẹran ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátapáta.

17. Nítorí Ọlọ́run ti fi sínú ọkàn wọn láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, láti ní inú kan, àti láti fi ìjọba wọn fún ẹranko náà, títí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò fi ṣẹ

18. Obìnrin tí ìwọ rí ní ìlú ńlá ni, tí ń jọba lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”

Ka pipe ipin Ìfihàn 17