Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 14:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mo sì wo, si kíyèsí i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí Òkè Síónì, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje-ó-lé ẹgbàájì ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú-orí wọn.

2. Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí aríwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá: mo sì gbọ́ àwọn oníháàpù, ń lù haàpù wọn.

3. Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin túntún níwájú ìtẹ́ náà, àti àwọn àgbà náà: kò sì sí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn òkè méje o lé ẹgbàájì ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá.

4. Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérì: nítorí tí wọ́n jẹ́ wúndíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a ràpadà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ̀-Àgùntàn náà.

5. A kò sì rí èké lẹ́nu wọn, wọn jẹ́ aláìlábùkù.

6. Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn ń fò ní àárin méjì ọ̀run, pẹ̀lú Ìyìn rere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.

7. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ogo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbàlẹ́ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti òkun, àti àwọn orísun omi!”

Ka pipe ipin Ìfihàn 14