Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìfihàn 12:13-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà tí dírágónì náà rí pé a lé òun lọ sí ilẹ ayé, ó sè inúnibíni sì obìnrin tí ó bí ọmọkùnrin náà.

14. A sì fi apá iyẹ́ méjì tí ìdì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí ihà, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà.

15. Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà ki o lè fí ìṣàn omi náà gbà á lọ.

16. Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ́ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dírágónì náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá.

17. Dírágónì náà sì bínú gidigidi sí obìnrin náà, ó sì lọ bá àwọn irú ọmọ rẹ̀ ìyókù jagun, tí wọ́n ń pa òfin Ọlọ́run mọ̀, tí wọn sì di ẹ̀rí Jésù mú, Ó sì dúró lórí ìyanrìn òkun.

Ka pipe ipin Ìfihàn 12