Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ó sì gba àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà wá sí ìhínyìí, láti de gbogbo àwọn ti ń pe orúkọ rẹ.”

15. Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Má a lọ; nítorí ohun-èlò ààyò ni òun jẹ́ fún mi, láti gbé orúkọ mi lọ sí iwájú àwọn aláìkọlà, àti àwọn ọba, àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

16. Nítorí èmi o fi gbogbo ìyà ti kò le ṣàìjẹ nítorí orúkọ mi hàn án.”

17. Ananíyà sì lọ, ó sì wọ ilé náà, nígbà tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé Sọ́ọ̀lù, ó sì wí pé, “Arákùnrin Sọ́ọ̀lù, Olúwa ni ó rán mi, Jésù tí ó fi ara hàn ọ lọ́nà tí ìwọ bá wá, kí ìwọ baà lè rìran, kí ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”

18. Lójúkan náà nǹkan kan ti ó dàbí ìpẹ́ sì bọ kúrò lójú rẹ̀, ó sì ríran; ó sì dìde, a sì bamitíìsì rẹ̀.

19. Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.Ṣọ́ọ̀lù sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Dámásíkù ní ọjọ́ púpọ̀

20. Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kírísítì nínú àwọn sínágógù pé, “Ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe.”

21. Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fòórò àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerúsálémù? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhìnyìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.”

22. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Dámásíkù, ó fi hàn pé, èyí ni Kírísítì náà.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 9