Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3:10-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Wọn sì mọ̀ pé òun ni ó ti jókòó tí ń ṣagbe lẹ́nu ọ̀nà Dáradára ti tẹ́ḿpìlì náà; hà, sì ṣe wọn, ẹnu sì yà wọn gidigidi sí ohun tí ó ṣe lára rẹ̀.

11. Bí arọ ti a mú láradá sì ti di Pétérù àti Jòhánù mú, gbogbo ènìyàn júmọ́ sure tọ̀ wọ́n lọ ni ìloro ti a ń pè ní ti Sólómónì, pẹ̀lú ìyàlẹ́nú ńlá.

12. Nígbà tí Pétérù sì rí i, ó dáhùn, ó wí fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, è é ṣe tí háà fi ń ṣe yín sí èyí? Tàbí è é ṣe ti ẹ̀yin fi tẹjúmọ́ wa, bí ẹni pé agbára tàbí ìwà mímọ́ wa ni àwa fi ṣe é ti ọkùnrin yìí fi ń rìn?

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 3