Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28:16-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Nígbà tí a sì dé Róòmù, olórí àwọn ọmọ ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀sọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láàyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń sọ́ ọ.

17. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù pe àwọn olórí Júù jọ: nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti se pé èmi kò se ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, ṣíbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Róòmù lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerúsálémù wá.

18. Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀ràn mi, wọ́n fẹ́ jọ̀wọ́ mi lọ́wọ́ lọ, nítorí tí wọn kò rí ẹ̀sùn kan tí ó tọ́ sí ikú pẹ̀lú mi.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 28