1. Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mélítà ni a ń pè eré-kùṣù náà.
2. Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn alàìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù.
3. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sì sa ìdí ìwọ̀nwọ̀n-igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́.
4. Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú àpànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láàyè.”
5. Òun sì gbọn ẹranko náà sínu iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é.
6. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣúbu lulẹ̀ kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.
7. Ní agbégbé ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọ́bílíù; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
8. Ó sì ṣe, baba Pọ́bílíù dubulẹ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Pọ́ọ̀lù wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá.
9. Nígbà tí èyí sì ṣe tán, àwọn ìyókù tí ó ni àrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá.
10. Wọ́n sì bu ọlá púpọ́ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.
11. Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú-omi kan èyí tí ó lo àkókò otútù ní erékùsù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú-omi ti Alekisáńdírà, èyí tí ó àmì èyí tí se òrìsà ìbejì ti Kásítórù òun Pólúkísù.
12. Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sírákúsì, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta.
13. Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Régíónì: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Pútéólì.
14. A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ́ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Róòmù.
15. Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúró pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjọ títí wọ́n fi dé Api-fórù àti sí ilé-èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígba tí Pọ́ọ̀lù sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le.
16. Nígbà tí a sì dé Róòmù, olórí àwọn ọmọ ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀sọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Pọ́ọ̀lù láàyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń sọ́ ọ.
17. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Pọ́ọ̀lù pe àwọn olórí Júù jọ: nígbà tí wọ́n sì péjọ, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ara, bí ó ti se pé èmi kò se ohun kan lòdì sí àwọn ènìyàn, tàbí sí àṣà àwọn baba wa, ṣíbẹ̀ wọ́n fi mí lé àwọn ara Róòmù lọ́wọ́ ní òǹdè láti Jerúsálémù wá.