Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 27:13-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúsù sì ń fẹ́ jẹ́jẹ́, tí wọn ṣèbí ọwọ́ àwọn tẹ ohun tí wọn ń wá, wọ́n ṣíkọ̀, wọn ń pá ẹ̀bá Kírétè lọ.

14. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ni ìjì ti a ń pè ni Éúrákúílò fẹ́ lù ú.

15. Nígbà ti ó sì ti gbé ọkọ̀-okun náà, ti kò sì lè dojúkọ ìjì yìí, a fi i sílẹ̀, ó ń gbá a lọ.

16. Nígbà tí ó sì gbá a lọ lábẹ́ erékùsù kan tí a ń pè Kíláúdà, ó di iṣẹ́ púpọ̀ kí a tó lè súnmọ́ ìgbàjà.

17. Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ́-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrin-dídẹ̀, wọn fi ìgbòkun sílẹ̀, bẹ́ẹ́ ni a sì ń gbá wa kiri.

18. Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ijọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀;

19. Ní ijọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun-èlò ọkọ̀ dànù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 27