Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 27:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Ítalì, wọn fi Pọ́ọ̀lù àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Júlíọ́sì, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Ọ̀gọ́sítúsì.

2. Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-okun Ádírámítíù kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí òkun Éṣíà, a ṣíkọ̀: Árísítakù, ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa.

3. Ní ijọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì. Júlíọ́sì sì ṣe inú rere sì Pọ́ọ̀lù, ó sì fún un láàyè kí ó máa tọ àwọn ọrẹ̀ rẹ̀ lọ kí wọn le se ìtọ́jú rẹ̀.

4. Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ níbẹ̀, a lọ lẹ́bá Kípírúsì, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì.

5. Nígbà tí a ré òkun Kílíkíà àti Paḿfílíà kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mírà ti Líkíà.

6. Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-okun Alekisáńdírà kan, ti ń lọ sí Ítalì; ó sì fi wa sínú rẹ̀.

7. Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọkánkán Nídúsì, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láàyè, a ba ẹ̀bá Kírétè lọ, lọ́kankán Sálímónì;

8. Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Láséà.

9. Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìn-àjò wa sì ti léwu gan-an nítorí nisinsinyìí ààwẹ̀ ti kọjá lọ, Pọ́ọ̀lù dá ìmọ̀ràn.

10. Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.”

11. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ́ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Pọ́ọ̀lù wí lọ.

12. Àti nítorí pé èbúté náà kò rọrùn láti lo àkókò òtútù níbẹ̀, àwọn púpọ̀ sí dámọ̀ràn pé, kí a lọ kúrò níbẹ̀, bóyá wọn ó lè làkàkà dé Fóníkè, tí i ṣe èbúté Kírétè ti ó kọjú sí òsì ìwọ̀-oorùn, àti ọ̀tún ìwọ̀-oorùn, láti lo àkókò òtútù níbẹ̀.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 27