1. Bí a sì ti pinnu rẹ̀ pé kí a wọ ọkọ̀ lọ sí Ítalì, wọn fi Pọ́ọ̀lù àti àwọn òǹdè mìíràn lé balógun ọ̀rún kan lọ́wọ́, ti a ń pè ní Júlíọ́sì, ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun Ọ̀gọ́sítúsì.
2. Nígbà tí a sì wọ ọkọ̀-okun Ádírámítíù kan, tí a fẹ́ lọ sí àwọn ìlú ti ó wà létí òkun Éṣíà, a ṣíkọ̀: Árísítakù, ará Makedóníà láti Tẹsalóníkà wà pẹ̀lú wa.
3. Ní ijọ́ kejì, a gúnlẹ̀ sí Sídónì. Júlíọ́sì sì ṣe inú rere sì Pọ́ọ̀lù, ó sì fún un láàyè kí ó máa tọ àwọn ọrẹ̀ rẹ̀ lọ kí wọn le se ìtọ́jú rẹ̀.
4. Nígbà tí a sì ṣíkọ̀ níbẹ̀, a lọ lẹ́bá Kípírúsì, nítorí tí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì.
5. Nígbà tí a ré òkun Kílíkíà àti Paḿfílíà kọjá, a gúnlẹ̀ sí Mírà ti Líkíà.
6. Níbẹ̀ ni balogun ọ̀rún sì rí ọkọ̀-okun Alekisáńdírà kan, ti ń lọ sí Ítalì; ó sì fi wa sínú rẹ̀.
7. Nígbà tí a ń lọ jẹ́jẹ́ ní ọjọ́ púpọ̀, ti a fi agbára káká dé ọkánkán Nídúsì, àti nítorí tí afẹ́fẹ́ kò fún wa láàyè, a ba ẹ̀bá Kírétè lọ, lọ́kankán Sálímónì;
8. Nígbà tí a sì fi agbára káká kọjá rẹ̀, a dé ibi tí a ń pè ní Èbùté Yíyanjú, tí ó súnmọ́ ìlú Láséà.
9. Nígbà ti a sì ti sọ ọjọ́ púpọ̀ nù, àti pé ìrìn-àjò wa sì ti léwu gan-an nítorí nisinsinyìí ààwẹ̀ ti kọjá lọ, Pọ́ọ̀lù dá ìmọ̀ràn.
10. Ó sì wí fún wọn pé, “Alàgbà, mo wòye pé ìṣíkọ̀ yìí yóò ní ewu, òfò púpọ̀ yóò sì wá, kì í ṣe kìkì ti ẹrù àti ti ọkọ̀, ṣùgbọ́n ti ọkàn wa pẹ̀lú.”
11. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún gba ti olórí ọkọ́ àti ti ọlọ́kọ̀ gbọ́, ju ohun wọ̀nyí tí Pọ́ọ̀lù wí lọ.