Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrin àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fí sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.

4. “Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerúsálémù.

5. Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisí ni èmi.

6. Nísinsìn yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26