Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àgírípà sì wí fún Pọ́ọ̀lù pé, “A fún ọ láàyè láti sọ tí ẹnu rẹ.” Nígbà náà ní Pọ́ọ̀lù ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé:

2. “Àgírípà ọba, inú èmi tìkárami dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi mi sùn,

3. pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrin àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fí sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi.

4. “Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerúsálémù.

5. Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisí ni èmi.

6. Nísinsìn yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́.

7. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí ì gbà. Ọba, n ítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 26