Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Fẹ́sítúsì sì wí pé, “Àgírípà Ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ mi ni Jerúsálémù àti Kesaríà níhìn yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láàyè mọ́.

25. Ṣùgbọ́n èmi rí i pé, kò se ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkárarẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Aúgọ́sítù, mo tí pinnu láti rán an lọ.

26. Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá ṣíwájú yín, àní ṣíwájú rẹ ọba Àgírípà, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí se wádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ.

27. Nítorí tí kò tọ́ ní ojú mi láti rán òǹdè, kí a má sì sọ ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 25