Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21:3-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nígbà tí àwa sì ń wo Sáípúrọ́sì lókèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Síríà, a sì gúnlẹ̀ ni Tírè; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù ṣílẹ̀.

4. Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ijọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Pọ́ọ̀lù pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerúsálémù.

5. Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà.

6. Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn.

7. Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tírè, àwa dé Pítólémáì; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ijọ́ kan.

8. Ní ijọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesaríà; nígbà tí á sì wọ ilé Fílípì ajíhìnrere tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.

9. Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúndíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀.

10. Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Jùdíà sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Ágábù.

11. Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Pọ́ọ̀lù, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹṣẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerúsálémù yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fí i lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ”

12. Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ ṣí Jerúsálémù.

13. Nígbà náà ni Pọ́ọ̀lù dàhun wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í se fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerúsálémù, nítorí orúkọ Jésù Olúwa.”

14. Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!”

15. Lẹ́yìn ijọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerúsálémù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21