Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21:27-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Nígbà tí ọjọ́ méje sì fẹ́rẹ̀ pé, tí àwọn Júù tí ó ti Éṣíà wá rí i ni tẹ́ḿpílì, wọ́n rú gbogbo àwọn ènìyàn sókè, wọ́n nawọ́ mú un.

28. Wọ́n ń kígbe wí pé, “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ gbà wá: Èyí ni ọkùnrin náà tí ń kọ́ gbogbo ènìyàn níbi gbogbo lòdì sí àwọn èniyan, àti sí òfin, àti sí ibí yìí: àti pẹ́lú ó sì mú àwọn ará Gíríkì wá sí tẹ́ḿpílì, ó sì tí ba ibi mímọ́ yìí jẹ́.”

29. Nítorí wọ́n tí rí Tírófímù ará Éfésù pẹ̀lú rẹ̀ ní ìlú, ẹni tí wọ́n ṣe bí Pọ́ọ̀lù mú wá sínú tẹ́ḿpílì.

30. Gbogbo ìlú sì wà ní ìrúkèrúdo, àwọn ènìyàn sì súré jọ: wọ́n sì mú Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú tẹ́ḿpílì: lójúkan náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.

31. Bí wọn sì ti ń wá ọ̀nà láti pa á, ìròyìn dé ọ̀dọ̀ olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun pé, gbogbo Jerúsálémù dàrú.

32. Lójúkan náà, ó sì ti mú àwọn ọmọ-ogun àti àwọn balógun ọ̀rún, ó sì súré sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ; nígbà tí wọ́n sì rí í olórí ogun àti àwọn ọmọ-ogun dẹ́kun lílù Pọ́ọ̀lù.

33. Nígbà náà ni olórí ogun súnmọ́ wọn, ó sì mú un, ó pàṣẹ pé kí a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é; ó sì bèèrè ẹni tí ó jẹ́, àti ohun tí ó ṣe.

34. Àwọn kan ń kígbe ohun kan, àwọn mìíràn ń kígbe ohun mìíràn nínú àwùjọ; nígbà tí kò sì lè mọ̀ ìdí pàtàkì fún ìrúkèrúdò náà, ó pàṣẹ kí wọ́n mú un lọ sínú àgọ́ àwọn ológun.

35. Nígbà tí ó sì dé orí àtẹ̀gùn, gbígbé ni a gbé e sókè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ogun nítorí ìwà-ipá àwọn ènìyàn.

36. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rọ́ tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Mú un kúrò!”

37. Bí wọ́n sì tí fẹ́rẹ̀ mú Pọ́ọ̀lù wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó wí fún olórí-ogun pé, “Èmi ha lè bá ọ sọ̀rọ̀ bí?”Ó sì dáhùn wí pé, “Ìwọ mọ èdè Gíríkì bí?

38. Ìwọ ha kọ ní ara Íjíbítì náà, tí ó ṣọ̀tẹ̀ ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ti ó sì ti mú ẹgbàajì ọkùnrin nínú àwọn tí í ṣe apànìyàn lẹ́yìn lọ ṣí ijù?”

39. Ṣùgbọ̀n Pọ́ọ̀lù sì wí pé, “Júù ní èmi jẹ́, ará Tásọ́sì ilú Kílíkíà, tí kì í ṣe ìlú yẹpẹrẹ kan, èmi ṣí bẹ̀ ọ, fún mi ní ààyè láti bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí sọ̀rọ̀!”

40. Nígbà tí ó sì tí fún un ní ààyè, Pọ́ọ̀lù dúró lórí àtẹ̀gùn, ó sì juwọ́ sí àwọn ènìyàn. Nígbà tí wọ́n sì dákẹ́rọ́rọ́, ó bá wọn sọ̀rọ̀ ní èdè Hébérù, wí pé:

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 21