Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:42-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn àpósítélì, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.

43. Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì ṣe.

44. Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn;

45. Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní.

46. Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹ́mpílì. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn.

47. Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojú rere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2