Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. A ti gbé ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó tu èyí tí ẹ̀yin rí àti gbọ́ nísinsìyìí sítá.

34. Nítorí Dáfídì kò gókè lọ sí ọ̀run ṣùgbọ́n òun tìkárarẹ̀ wí pé,“ ‘Olúwa wí fún Olúwa mi pé:“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi

35. títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀ta rẹdí àpótí ìtìsẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ.” ’

36. “Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jésù náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, se Olúwa àti Kírísítì.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 2