Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18:10-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.”

11. Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdun kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrin wọn.

12. Nígbà tí Gálíónì sì jẹ báalẹ̀ Ákáyà, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dide sí Pọ́ọ̀lù wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́.

13. Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.”

14. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fẹ́ dáhùn, Gálíónì wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹyin Júù;

15. Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nipa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrará yín; nítorí tí èmi kò fẹ ṣe onídàjọ́ nǹkan báwọ̀nyí.”

16. Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́.

17. Gbogbo àwọn Gíríkì sì mú Sósìténì, olórí ṣínágógù, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gálíónì kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí.

18. Pọ́ọ̀lù sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀-ojúomi lọ si Síríà, àti Pìrìsílà àti Àkúílà pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kéníkíríà: nítorí tí o tí jẹ́jẹ̀ẹ́.

19. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éféṣù, ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀: ṣùgbọ́n òun tìkararẹ̀ wọ inú Sínágọ́gù lọ, ó sì bá àwọn Júù fí ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀.

20. Nígbà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó bá àwọn jókòó díẹ̀ sí i, ó kọ̀;

21. Ṣùgbọ́n ó dágbére fún wọn, ó sì wí pé, (Èmi kò gbọdọ̀ má ṣe àjọ ọdún tí ń bọ̀ yìí ni Jerúsálémù bí ó tí wù kí ó rí: ṣùgbọ́n) “Èmi ó tún padà tọ̀ yín wá, bí Ọlọ́run bá fẹ́.” Ó sì ṣíkọ̀ láti Éfésù.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 18