Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17:4-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í se díẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn si fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ìta ènìyàn mọ́ra, wọ́n gbá ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jásónì, wọ́n ń fẹ́ láti mú wọn jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.

6. Nìgbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò wá sí ìhínyìí pẹ̀lú.

7. Àwọn ẹni tí Jásónì gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kéṣárì, wí pé, ọba mìíràn kan wà, Jéṣù.”

8. Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ni ìbàlẹ̀ àyà nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.

9. Nígbà tí wọ́n sì gbà ògo lọ́wọ́ Jásónì àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n ṣílẹ̀ lọ.

10. Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Pọ́ọ̀lù àti Ṣílà lọ ṣí Béróéá lóru: nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú ṣínágógù àwọn Júù lọ.

11. Àwọn wọ̀nyí sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalóníkà lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé-mímọ̀ lójoojúmọ́ bí ǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀.

12. Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Gíríkì ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin, kì í ṣe díẹ̀.

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalóníkà mọ̀ pé, Pọ́ọ̀lù ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Béreóà, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè.

14. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Pọ́ọ̀lù jáde lọ́gán láti lọ títí de òkun: ṣùgbọ́n Sílà àti Tímótíù dúró ṣíbẹ̀.

15. Àwọn tí ó sin Pọ́ọ̀lù wá sì mú un lọ títí dé Átẹ́nì; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sílà àti Tímótíù pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

16. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró dè wọ́n ni Aténì, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà.

17. Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sínágógù, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́.

18. Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Épíkúrè àti tí àwọn Sítííkì pàdé rẹ̀. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí ń wàásù Jésù, àti àjíǹde fún wọn.”

19. Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ ṣí Áréópágù, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ titun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?

20. Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá si etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.”

21. Nítorí gbogbo àwọn ará Áténì, àti àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí ki a máa gbọ́ ohun titun lọ.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17