Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17:15-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Àwọn tí ó sin Pọ́ọ̀lù wá sì mú un lọ títí dé Átẹ́nì; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sílà àti Tímótíù pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

16. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dúró dè wọ́n ni Aténì, ẹ̀mí rẹ̀ ru nínú rẹ̀, nígbà tí ó rí pé ìlú náà kún fún òrìṣà.

17. Nítorí náà ó ń bá àwọn Júù fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú Sínágógù, àti àwọn olùfọkànsìn, àti àwọn tí ó ń bá pàdé lọ́jà lójoojúmọ́.

18. Nínú àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Épíkúrè àti tí àwọn Sítííkì pàdé rẹ̀. Àwọn kan si ń wí pé, “Kín ni aláhesọ yìí yóò rí wí?” Àwọn mìíràn sì wí pé, “Ó dàbí ń wàásù Jésù, àti àjíǹde fún wọn.”

19. Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fà á lọ ṣí Áréópágù, wọ́n wí pé, “A ha lè mọ̀ kín ni ẹ̀kọ́ titun tí ìwọ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́?

20. Nítorí tí ìwọ mú ohun àjèjì wá si etí wa: àwa sì ń fẹ́ mọ̀ kín ni ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí.”

21. Nítorí gbogbo àwọn ará Áténì, àti àwọn àlejò tí ń ṣe àtìpó níbẹ̀ kì í ṣe ohun mìíràn jù kí a máa sọ tàbí ki a máa gbọ́ ohun titun lọ.

22. Pọ́ọ̀lù si dìde dúró láàrin Áréópágù, ó ní, “Ẹ̀yin ará Áténì, mo wòye pé ní ohun gbogbo ẹ kún fún onírúurú ìsìn jù.

23. Nítorí bí mo ti ń kọjá lọ, tí mo wo àwọn ohun tí ẹ̀yin ń sìn, mo sì rí pẹpẹ kan tí a kọ àkọlé yìí ṣí, ‘FÚN ỌLỌ́RUN ÀÌMỌ̀.’ Ǹjẹ́ ẹni tí ẹyin ń sìn ni àìmọ̀ òun náà ni èmi ń ṣọ fún yin.

24. “Ọlọ́run náà tí ó dá ayé àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, òun náà tí í ṣe Olúwa ọ̀run àti ayé, kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́;

25. Bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ènìyàn sìn ín, bí ẹni pé ó ń fẹ́ nǹkan, òun ni ó fi ìyè àti èémí àti ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17