Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí wọn sì ti kọjá Áḿfípólì àti Apolóníà, wọ́n wá sí Tẹsalóníkà, níbi tí sínágọ́gù àwọn Júù wà:

2. Àti Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé-mímọ́.

3. Ó ń túmọ̀, ó sí n fihàn pé, Kíríṣítì kò lè sàìmá jìyà, kí o sì jínde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jéṣu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kírísítì náà.”

4. A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í se díẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn si fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ìta ènìyàn mọ́ra, wọ́n gbá ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jásónì, wọ́n ń fẹ́ láti mú wọn jáde tọ àwọn ènìyàn lọ.

6. Nìgbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò wá sí ìhínyìí pẹ̀lú.

7. Àwọn ẹni tí Jásónì gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kéṣárì, wí pé, ọba mìíràn kan wà, Jéṣù.”

8. Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ni ìbàlẹ̀ àyà nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 17