Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15:11-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ṣùgbọ́n àwa gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Olúwa Jésù àwa ó là, gẹ́gẹ́ bí àwọn.”

12. Gbogbo àjọ sí dákẹ́, wọ́n sì fi ẹ̀rí sí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọn ń ròyìn iṣẹ́-àṣẹ àti iṣẹ́-àmì tí Ọlọ́run tí ti ọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn aláìkọlà.

13. Lẹ̀yìn tí wọn sì dákẹ́, Jákọ́bù dáhùn, wí pé, “Ará, ẹ gbọ́ tèmi:

14. Símóòní ti róyìn bí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ bojúwo àwọn aláìkọlà, láti yàn ènìyàn nínú wọn fún orúkọ rẹ̀.

15. Báyìí ni ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bá ṣe dédé; bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

16. “ ‘Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni èmi ó padà,èmi ó sì tún àgọ́ Dáfídì pa tí ó ti wó lulẹ̀:èmi ó sì tún ahoro rẹ̀ kọ́,èmi ó sì gbé e ró:

17. kí àwọn ènìyàn ìyókù lè máa wá Olúwa,àti gbogbo àwọn aláìkọlà tí a ń fi orúkọ mi pè.’ni Olúwa wí, ta ni ó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí

18. Ní Olúwa wí, ẹni tí ó sọ gbogbonǹkan wọ̀nyí di mímọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ wá,

19. “Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn tèmi ni pé, kí a máa ṣe yọ àwọn ti aláìkọlà ti ó yípadà sí Ọlọ́run lẹ́nu.

20. Ṣùgbọ́n kí a kọ̀wé si wọn, kí wọ́n fà sẹ̀hín kúrò nínú èérí òrìṣà, àti kúrò nínú àgbèrè, àti nínú ẹ̀jẹ̀.

21. Mósè nígbà àtijọ́, sá ní àwọn ti ń wàásù rẹ̀, ni ìlú gbogbo, a máa ń kà á nínú sínágọ́gù ni ọjọ́jọ́ ìsinmi.”

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 15