Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:42-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

42. Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.

43. Nígbà tí wọn sì jáde nínú sínágọ́gù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀le Pọ́ọ̀lù àti Básébà, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

44. Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ pejọ́ tan lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

45. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Pọ́ọ̀lù ń sọ.

46. Pọ́ọ̀lù àti Básébà sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.

47. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti paṣẹ̀ fún wa pé:“ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà,kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”

48. Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́.

49. A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbégbé náà.

50. Ṣùgbọ́n àwọn Júù rú àwọn obìnrin olùfọkànsìn àti ọlọ́lá sókè àti àwọn àgbà ìlú náà, wọ́n sì gbé inúnibíni dìde sí Pọ́ọ̀lù àti Básébà, wọ́n sì ṣí wọn kúrò ni agbégbé wọn.

51. Ṣùgbọ́n wọ́n gbọn eruku ẹsẹ̀ wọn sí wọn, wọn sì wá sí Ikóníónì.

52. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn si kún fún ayọ̀ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13