Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:31-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ó sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Gálílì wá sí Jerúsálémù, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsìn yìí fún àwọn ènìyàn.

32. “Àwa sì mú ìyìn rere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,

33. Èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jésù dìde: Bí a sì ti kọwé rẹ̀ nínú Sáàmù kejì pé:“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;lónìí ni mo bí ọ.’

34. Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyí pé:“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dáfídì, tí ó dájú.’

35. Nítorí ó sì wí nínú Sáàmù mìíràn pẹ̀lú pé:“ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

36. “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dáfídì ti sin ìran rẹ tan nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.

37. Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́

38. “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jésù yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.

39. Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè.

40. Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:

41. “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;nítorí èmi ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́jọ́ yín,iṣẹ́ tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́bí ẹnìkan tilẹ̀ ròyìn rẹ̀ fún yín.’ ”

42. Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.

43. Nígbà tí wọn sì jáde nínú sínágọ́gù, ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù àti nínú àwọn olùfọkànsìn aláwọ̀ṣe Júù tẹ̀le Pọ́ọ̀lù àti Básébà, àwọn ẹni tí ó bá wọn sọ̀rọ̀ tí wọ́n sì rọ̀ wọ́n láti dúró nínú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

44. Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, gbogbo ìlú sí fẹ́rẹ̀ pejọ́ tan lati gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

45. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù rí ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, wọ́n kún fún owú, wọ́n ń sọ̀rọ̀-òdì sí ohun ti Pọ́ọ̀lù ń sọ.

46. Pọ́ọ̀lù àti Básébà sì dá wọn lóhùn láìbẹ̀rù pé, “Ẹ̀yin ni ó tọ́ sí pé ki a kọ́kọ́ sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ti ta á nù, tí ẹ sì ka ara yín sí aláìyẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó, àwa yípadà sọ́dọ̀ àwọn aláìkọlà.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13