Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Áńtíókù; Bánábà àti Síméónì tí a ń pè ni Nígérì, àti Lúkíọ́sì ará Kírénè, àti Mánáénì (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Hẹ́ródù Tétírákì) àti Ṣọ́ọ̀lù.

2. Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Bánábà àti Ṣọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!”

3. Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ.

4. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn mẹ́jẹ̀èjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀-ojú omi lọ sí Sáípúrọ́sì.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13