Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní àkókò ìgbà náà ni Hérọ́dù ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan lójú nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú.

2. Ó sì fi idà pa Jákọ́bù arakùnrin Jòhánù.

3. Nígbà tí ó sì rí pé èyí ó dùn mọ́ àwọn Júù nińu, ó sì nawọ́ mú Pétérù pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà ọjọ́ àkàrà àìwú.

4. Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Hẹ́rọ́dù ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrekọjá fún ìdájọ́.

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 12