Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. “Èmi wà ni ìlú Jópà, mo ń gbàdúrà, mo rí ìran kan lójúran. Ohun èlò kan sọ̀kalẹ̀ bí ewé tákàdá ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá; ó sì wá títí de ọ̀dọ̀ mi.

6. Mo tẹjúmọ́ ọn, mo sì fiyèsí i, mo sí rí ẹran ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin, àti ẹranko ìgbẹ́, àti ohun tí ń rákò, àti ẹyẹ ojú ọ̀run.

7. Mo sì gbọ́ ohùn kan ti ó fọ̀ sí mi pé, ‘Dìde, Pétérù: máa pa, kí ó sì máa jẹ.’

8. “Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘Àgbẹdọ̀, Olúwa! nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láí.’

Ka pipe ipin Ìṣe Àwọn Àpósítélì 11