Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 4:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin.

22. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Ábúráhámù ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.

23. Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira-obìnrin ni a bí nípa ìlérí.

24. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní méjẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sínáì wá, tí a bí lóko-ẹrú, tí í ṣe Hágárì.

25. Nítorí Hágárì yìí ni òkè Sínáì Árábíà, tí ó sì dúró fún Jerúsálémù tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko-ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n Jerúsálémù ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.

27. Nítorí a ti kọ ọ́ pé,“Má a yọ̀, ìwọ obìnrin àgàntí kò bímọ,bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,ìwọ tí kò rọbí rí;nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”

28. Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Ísáákì.

29. Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsìnyìí.

30. Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrú-bìnrin náà jáde àti ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ ẹrú-bìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira-obìnrin jogún pọ̀.”

31. Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrú-bìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.

Ka pipe ipin Gálátíà 4