Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 4:20-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsìnyìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín.

21. Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin.

22. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Ábúráhámù ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.

23. Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira-obìnrin ni a bí nípa ìlérí.

24. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní méjẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sínáì wá, tí a bí lóko-ẹrú, tí í ṣe Hágárì.

25. Nítorí Hágárì yìí ni òkè Sínáì Árábíà, tí ó sì dúró fún Jerúsálémù tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko-ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n Jerúsálémù ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.

27. Nítorí a ti kọ ọ́ pé,“Má a yọ̀, ìwọ obìnrin àgàntí kò bímọ,bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè,ìwọ tí kò rọbí rí;nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”

28. Ǹjẹ́ ará, ọmọ ìlérí ni àwa gẹ́gẹ́ bí Ísáákì.

29. Ṣùgbọ́n bí èyí tí a bí nípa ti ara ti ṣe inúnibíni nígbà náà sí èyí tí a bí nípa ti Ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni nísinsìnyìí.

30. Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ha ti wí, “Lé ẹrú-bìnrin náà jáde àti ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ ẹrú-bìnrin kì yóò bá ọmọ òmìnira-obìnrin jogún pọ̀.”

31. Nítorí náà, ará, àwa kì í ṣe ọmọ ẹrú-bìnrin bí kò ṣe ti òmìnira obìnrin.

Ka pipe ipin Gálátíà 4