Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 4:12-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi: nítorí èmi dà bí ẹ̀yin: èyin kò ṣe mí ní ibi kan.

13. Ẹ̀yin mọ̀ pé nínú àìlera ni mo wàásù ìhìnrere fún yín ní àkọ́kọ́.

14. Èyí tí ó sì jẹ́ ìdánwò fún yín ní ara mi ni ẹ kò kẹ́gàn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì kọ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, àní bí Kírísítì Jésù.

15. Ǹjẹ́ ayọ̀ yín ìgbà náà há dà? Nítorí mo gba ẹ̀rí yín pé, ìbá ṣe é ṣe, ẹ̀ ò bá yọ ojú yín jáde, ẹ̀ bá sì fi wọ́n fún mi.

16. Ǹjẹ́ mo há di ọ̀ta yín nítorí mo sọ òtítọ́ fún yín bí?

17. Wọ́n ń fi ìtara wá yin, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún rere; wọ́n ń fẹ́ já yin kúrò, kí ẹ̀yin lè máa wá wọn.

18. Ṣùgbọ́n ó dára láti máa fi ìtara wáni fún rere nígbà gbogbo, kì í sìí ṣe nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nìkan.

19. Ẹ̀yin ọmọ mi kékèké, ẹ̀yin tí mo tún ń rọbí títí a ó fi ṣe ẹ̀dá Kírísítì nínú yín.

20. Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsìnyìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín.

21. Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin.

22. Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Ábúráhámù ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.

23. Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara: ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira-obìnrin ni a bí nípa ìlérí.

24. Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní méjẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sínáì wá, tí a bí lóko-ẹrú, tí í ṣe Hágárì.

25. Nítorí Hágárì yìí ni òkè Sínáì Árábíà, tí ó sì dúró fún Jerúsálémù tí ó wà nísinsin yìí, tí ó sì wà lóko-ẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀.

26. Ṣùgbọ́n Jerúsálémù ti òkè jẹ́ òmìnira, èyí tí í ṣe ìyá wa.

Ka pipe ipin Gálátíà 4