Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 3:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùkọ́ni mọ́.

26. Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.

27. Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti baptisti sínú Kírísítì ti gbé Kírísítì wọ̀.

28. Kò le sí Júù tàbí Gíríkì, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí ọbìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kírísítì Jésù.

29. Bí ẹ̀yin bá sì jẹ́ ti Kírísítì, ǹjẹ́ ẹ̀yin ní irú-ọmọ Ábúráhámù, àti àrólé gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

Ka pipe ipin Gálátíà 3