Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 3:18-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nítorí bí ìjogún náà bá ṣe ti òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Ábúráhámù nípa ìlérí.

19. Ǹjẹ́ kí há ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipaṣẹ̀ àwọn áńgẹ́lì lànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá.

20. Ǹjẹ́ alárinà láàrin ẹgbẹ́ tí ó ju ọ̀kan ṣoṣo lọ; ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.

21. Nítorí náà òfín ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà.

22. Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ti sé gbogbo nǹkan mọ́ sábẹ́ ẹṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23. Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fi hàn.

24. Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùkọ́ni láti múni wá sọ́dọ̀ Kírísítì, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́.

25. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí ìgbàgbọ́ ti dé, àwa kò sí lábẹ́ olùkọ́ni mọ́.

26. Nítorí pé ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín, nípa ìgbàgbọ́ nínú Kírísítì Jésù.

27. Nítorí pé iye ẹ̀yin tí a ti baptisti sínú Kírísítì ti gbé Kírísítì wọ̀.

28. Kò le sí Júù tàbí Gíríkì, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí ọbìnrin nítorí pé ọ̀kan ni nínú Kírísítì Jésù.

Ka pipe ipin Gálátíà 3