Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 3:17-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Èyí tí mò ń wí ni pé: Májẹ̀mu tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣáájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, tí à bá fi mú ìlérí náà di aláìlágbára.

18. Nítorí bí ìjogún náà bá ṣe ti òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Ábúráhámù nípa ìlérí.

19. Ǹjẹ́ kí há ni òfin? A fi kún un nítorí ìrékọjá títí irú-ọmọ tí a ti ṣe ìlérí fún yóò fi dé; a sì tipaṣẹ̀ àwọn áńgẹ́lì lànà rẹ̀ láti ọwọ́ alárinà kan wá.

20. Ǹjẹ́ alárinà láàrin ẹgbẹ́ tí ó ju ọ̀kan ṣoṣo lọ; ṣùgbọ́n ọ̀kan ni Ọlọ́run.

21. Nítorí náà òfín ha lòdì sí àwọn ìlérí Ọlọ́run bí? Kí a má rí i; Nítorí ìbá ṣe pé a ti fi òfin kan fún ni tí ó lágbára láti sọni di ààyè nítòótọ́ òdodo ìbá ti tipasẹ̀ òfin wà.

22. Ṣùgbọ́n ìwé-mímọ́ ti sé gbogbo nǹkan mọ́ sábẹ́ ẹṣẹ̀, kí a lè fi ìlérí nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì fún àwọn tí ó gbàgbọ́.

23. Ṣùgbọ́n kí ìgbàgbọ́ tó dé, a ti pa wá mọ́ lábẹ́ òfin, a sì sé wa mọ́ de ìgbàgbọ́ tí a ń bọ̀ wá fi hàn.

24. Nítorí náà òfin ti jẹ́ olùkọ́ni láti múni wá sọ́dọ̀ Kírísítì, kí a lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́.

Ka pipe ipin Gálátíà 3