Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 1:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Síríà àti ti Kílíkáíà;

22. Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kírísítì ni Jùdíà:

23. Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsìn yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.”

24. Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Ka pipe ipin Gálátíà 1