Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Gálátíà 1:18-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, nígbà náà ni mo gòkè lọ sì Jerúsálémù láti lọ kì Pétérù, mo sì gbé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún,

19. Èmi kò ri ẹlòmíràn nínú àwọn tí ó jẹ́ Àpósítélì, bí kò ṣe Jákọ́bù arákùnrin Olúwa.

20. Nǹkan tí èmi ń kọ̀wé sí yín yìí kíyèsí i, níwájú Ọlọ́run èmi kò ṣèké.

21. Lẹ́yìn náà mo sì wá sí agbègbè Síríà àti ti Kílíkáíà;

22. Mo sì jẹ́ ẹni tí a kò mọ̀ lójú fún àwọn ìjọ tí ó wà nínú Kírísítì ni Jùdíà:

23. Wọ́n kàn gbọ́ ìròyìn wí pé, “Ẹni tí ó tí ń ṣe inúnibíni sí wa rí, ní ìsinsìn yìí ti ń wàásù ìgbàgbọ́ náà tí ó ti gbìyànjú láti bàjẹ́ nígbà kan rí.”

24. Wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Ka pipe ipin Gálátíà 1