Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 3:9-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ayébáyé nínú Ọlọ́run, ẹni tí o dá ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì:

10. Kí a bà á lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onirúuru ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,

11. gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àtayébáyé tí ó ti pinnu nínú Kírísítì Jésù Olúwa wa:

12. Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.

13. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, tíi ṣe ògo yín.

14. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eekún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.

15. Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.

16. Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ mú ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

17. Kí Kírísítì lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́;

18. Kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga náàìfẹ́ Kírísítì jẹ́.

19. Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kírísitì yìí tí o ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọ́run kún yín.

20. Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.

21. Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kírísítì Jésù títí ìrandíran gbogbo, ayé àìnípẹ̀kun, Àmí.

Ka pipe ipin Éfésù 3