Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 3:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kírísítì.

5. Èyí tí a kò í tíì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn àpostélì rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;

6. Pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kírísítì Jésù nípa ìyìn rere;

7. Ìránṣẹ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fifún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

8. Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídi ọ̀rọ̀ Kírísítì fún àwọn aláìkọlà;

9. Àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ayébáyé nínú Ọlọ́run, ẹni tí o dá ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì:

10. Kí a bà á lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onirúuru ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,

11. gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àtayébáyé tí ó ti pinnu nínú Kírísítì Jésù Olúwa wa:

12. Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.

Ka pipe ipin Éfésù 3