Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Éfésù 3:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí èyí náà ni èmi Pọ́ọ̀lù ṣe di òǹdè Jésù Kírísítì nítorí ẹ̀yin aláìkọlà,

2. Bí ẹ̀yin bá tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fifún mi fún yín;

3. Bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni sókí,

4. Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kírísítì.

5. Èyí tí a kò í tíì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn àpostélì rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;

6. Pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kírísítì Jésù nípa ìyìn rere;

7. Ìránṣẹ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fifún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

8. Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídi ọ̀rọ̀ Kírísítì fún àwọn aláìkọlà;

9. Àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ayébáyé nínú Ọlọ́run, ẹni tí o dá ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì:

Ka pipe ipin Éfésù 3