Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 2:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe Balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.

11. Nítorí àti ẹni tí ń sọni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin.

12. Wí pé,“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,ni àárin ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”

13. Àti pẹ̀lú,“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”Àti pẹ̀lú,“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”

14. Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábàápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábàápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni Èṣù.

15. Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọjọ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù.

16. Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn ańgẹ́lì ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Ábúráhámù ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún.

17. Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòótọ́ Olórí Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn.

18. Nítorí níwọ̀n bí òun tìkararẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 2