Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 12:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélomélo ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndè sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá:

26. Ohùn ẹni ti o mi ayé nígbà náà: ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti ṣe ìlérí, wí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi ki yóò mi kìkì ayé nìkan, ṣùgbọ́n ọ̀run pẹ̀lú.”

27. Àti ọ̀rọ̀ yìí, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ìtumọ̀ rẹ̀ ni, mímú àwọn ohun wọ̀nyí ti a ń mì kúrò, bí ohun tí a ti dá, kí àwọn ohun tí a kò lè mì lè wà síbẹ̀.

28. Nítorí náà bí àwa tí ń gbà ilẹ̀ ọba ti a kò lè mì, ẹ jẹ́ kí a ni oore-ọfẹ́ nípa èyí ti a fi lè máa sin Ọlọ́run ni ìtẹ́tẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ìbẹ̀rù rẹ̀.

29. Nítorí pé, “Ọlọ́run wa, iná ti ń jó nírun ni.”

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 12