Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nítorí náà bí a ti fi ikúukùu àwọsánmà tí o kún fún àwọn ẹlẹ́ri tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tí si apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,

2. Kí a máa wo Jésù Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jóko lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.

3. Má a ro ti ẹni tí ó faradà irú sọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má baa rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

4. Ẹ̀yin kò sáà tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀ nínú ìjakadi yín.

Ka pipe ipin Àwọn Hébérù 12